Jump to content

Ìpínlẹ̀ Kogí

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
(Àtúnjúwe láti Ipinle Kogi)
Ipinle Kogi
State nickname: The Confluence State
Location
Location of Kogi State in Nigeria
Statistics
Governor
(List)
Ibrahim Idris (PDP)
Date Created 27 August 1991
Capital Lokoja
Area 29,833 km²
Ranked 13th
Population
1991 Census
2005 estimate
Ranked 24th
2,099,046
3,595,789
ISO 3166-2 NG-KO


Ìpínlẹ̀ Kogí jẹ́ ìpínlẹ̀ kan ní àáríngbùngbùn àríwá orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, tí ó pín ààlà sí ìlà-oòrùn pẹ̀lú àwọn Ìpínlẹ̀ Ekiti àti Kwara, sí àríwá ní agbègbè olú-ìlú, sí àríwá-ìlà-oòrùn pẹ̀lú Ìpínlẹ̀ Nasarawa, sí àríwá-ìwọ̀ oòrùn pẹ̀lú Ìpínlẹ̀ Niger, sí gúúsù-ìwọ̀ oòrùn pẹ̀lú àwọn Ìpínlẹ̀ Edo àti Ondo, sí gúúsù-ìlà-oòrùn pẹ̀lú àwọn Ìpínlẹ̀ Anambra àti Enugu, àti sí ìwọ̀ oòrùn pẹ̀lú Ìpínlẹ̀ Benue. Ó jẹ́ ìpínlẹ̀ kan ṣoṣo tí ó pín ààlà pẹ̀lú àwọn ìpínlẹ̀ mẹ́wàá mìíràn orílẹ̀ èdè Nàìjíríà. Orúkọ Hausa fún odò—kogi. Wọ́n dá Ìpínlẹ̀ Kogí sílẹ̀ látara àwọn apá kan ìpínlẹ̀ Benue, ìpínlẹ̀ Niger, àti ìpínlẹ̀ Kwara ní ọjọ́ kẹtàdínlọ́gbọ̀n oṣù kẹ́jọ, ọdún 1991.[1][2] Orúkọ inagijẹ ìpínlẹ̀ "Confluence State"-(Ìwọ̀núbọ̀nú ìpínlẹ̀) náà látàrí ìdàpọ̀ odò Niger àti odò Benue wáyé ní tòsí olú-ìlú rẹ̀ tí ń ṣe Lokoja.[3]

Laaarin àwọn ìpínlẹ̀ mẹ́rìndínlógójì ti orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, ìpínlẹ̀ Kogi jẹ́ ìpínlẹ̀ ẹlẹ́ẹ̀kẹtàlá tí ó gbòòrò jùlọ ní ààyè tàbí agbègbè àti ẹlẹ́ẹ̀kejìlá ní iye pẹ̀lú ènìyàn tí ó tó mílíọ́nnù mẹ́rin-àbọ̀ gẹ́gẹ́ bí àbájáde ọdún 2016.[4]

Àwọn olùgbé ìpínlẹ̀ Kogi láti bí ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn kúnfún àwọn oríṣiríṣi ẹ̀yà pẹ̀lú Ebira, Gbagyi, àti Nupe (pàápàá jùlọ Bassa Nge, Kakanda, àti ìdá-ẹ̀ya Kupa) ní àwọn gbàgede ìpínlẹ náà; Agatu, Basa-Komo, Idoma, Igala, àti Igbo ní ìlà-oòrùn; àti Yoruba (pàápàá jùlọ Okun, Ogori, Oworo, àti ìdá-ẹ̀ya Magongo) ní ìwọ̀ oòrùn.


  1. Onyeakagbu, Adaobi. "See how all the 36 Nigerian states got their names". Pulse.ng. Archived from the original on 11 August 2022. Retrieved 25 December 2021. 
  2. "This is how the 36 states were created". Pulse.ng. Retrieved 22 December 2021. 
  3. A. B. MAMMAN, J.O. OYEBANJI (2000). Nigeria: A people united, A Future Assured. pp. 333. 
  4. "Population 2006-2016". National Bureau of Statistics. Retrieved 21 December 2021.